KINI Ό N ṢẸLẸ̀ NÍBI?
Ṣé o lé fojú inú wò bí àwọn ìlú atí ìlú nlá wa ṣe rí tẹlẹ?


Ilé kíkọ ti rọpò àwọn irà ti Mangrove.
“Dojúkọ mí kín dojúkọọ (Face me I face you)” ní a pè ní ilẹ kan níbíti ọpọlọpọ àwọn ìdílé ún gbé ní pẹkípẹkí àti pé wọn n gbé ní àwọn yàrá tó kọjú sí ara wọn. Bí àwọn ènìyàn tí ún pọ sii bẹẹní àwọn ìlú nlá wa dí (kún) síi.

Erékúsù Èkó nígbàkán jẹ ilẹ oko atí ilé fún àwọn apẹja atí àwọn ọdẹ ọọní. Ní ìgbà pípẹ púpọ sẹhìn ó jẹ ilé fún àwọn ẹfọn omi.
Nígbàtí Nígeria gba òmìníra kúrò lọwọ ìjọba amúnísìn ti Ìlú Gẹẹsì ní ọdún 1960 àwọn ènìyàn jẹ mílíọnù 45 (márùndíladóta). Ní bayi ó jẹ (200) Igba mílíọnù. Ní 2050 olùgbé (Iye ènìyàn) yóò jẹ 400 (Irinwó mílíọnù). Àwọn ènìyàn mẹtàlélọgọta mílíọnù káàkiri Nígeria kò ní àfànní sí omi tó dára (mọ). Èyí yoo túmọ sí pé omi mímọ yoo kéré atí ilẹ-ògbìn tí ó kéré sí. Àwọn àrùn yoo tàn kálè ní rọọrùn.

“ọọní” ní New York, nípasẹ olùyàwòrán ògiri PANGOLIN.

Ní àyíká Èkó àwọn lagoonu ti kún fún àwọn ọọní atí ẹja nígbà kan ríi.


Ablade Glover jẹ olùyàwòrán Ghàníàn kan ti ó ya àwọn iṣẹlẹ àwọn ìlú wa ti ó kúnjù. Níbití a ti ní àwọn ìlú nla sií bayi ẹfòn omi ló kún ibè nígbà kan rií.
Àwọn odò wa atí àwọn irà yẹ kí ó jẹ ilé fún ẹfòn omi, Erinmi kékeré, àwọn ọọni atí erin.



Díẹ nínú àwọn ẹranko yoo parun láìpẹ. Nígbàtí èyí bá ṣẹlẹ kíni yóò jẹ ti wa? Gbogbo wa gbáralé ara wa. A nílò latí dáàbò bo àwọn ẹranko ìgbẹ wa kúrò lówó àwọn ọdẹ nítorí èyí yóò tún jẹ kí wọn parun. Kí ába lè máa gbé ìgbé ayé ìlera ó jẹ nkan pàtàkì latí dábòbo agbègbè wa atí àwọn íbùgbé tí èdá abèmí wà.
