KÓ GBOGBO RẸ SÍLẸ KÍ O SÌ YÀWÒRÁN
Erin Kìí Gbàgbé

Jẹ kí á ya àwòrán kí á ṣe eré ìrántí tiwa.

Erin ní àwọn ìrántí ìyàlẹnu àti pé ó lè rántí àwọn ibi tí ó dára jùlọ látiwá oúnjẹ àti omi, ṣe ìdánimọ àwọn ọrẹ àti ọtá wọn ti ọpọlọpọ ọdún.

1.Gé àwọn ègé ìwé onígun mẹrin kan.

2. Ya àwọn ẹranko orísìí méjì lórí àwọn onígun mẹrin rẹ.

Jẹ kí á ṣeré!

  1. Da gbogbo àwọn káádíì orísìí méjì rẹ yìí pọ kí o sì dà wọn sílẹ lórí tábílì kan, kó kọjú dalẹ.
  2. Jẹ kí àwọn òsèré/eléré yí káádíì yìí pọ ní sísẹ ntẹlé, tí àwọn káádíì orísìí méjì tí wọn mú bá papọ, òsèré ni óni wọn.
  3. Tí àwọn káádíì yìí kò bá bá ara wọn mu, oní láti do jú àwọn káádíì yí bolẹ padà.
  4. ẹtàn ní láti rántí ibití irú àwọn káádíì orísìí méjì yìí wà.
  5. Ènìyàn tí ó ní àwọn orísìí méjì púpọ jùlọ ní òpin eré ní olúborí!
Copyright Polly Alakija