NOOTÍ ÀTÍ BOOTU
Báwo?

Onímọ̀ sáyẹ́ńsì Aǹkárá!

Gbogbo wa ni a nífẹ̀ẹ́ ANKARA. A nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà àtúntẹ̀ tí o máa ń sọ ìtàn àtìgbàdégbà.

Kíni o rí nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí?

Díẹ̀ nínú àwọn ìdọ̀tí máa ń léfὸὁ lojú omi, díẹ̀ nínú wọ́n máa n rì sí ìsàlẹ̀ omi.

E jẹ́ kí a wo ohun tí o ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀nà ojú omi wa nígbàtí a bá da ìdọ̀tí wa sínú àwọn kὸtὸ ìdaminù, odὸ kékeré àti odὸ ńlá.

Ìwọ yὁὸ nílὸ:

Àwọn ike omi elẹ́gbin

Omi

Orísirísi àwọn ohun èlὸ: epo, iyanrìn, ìrẹsì, ẹ̀wà, àwọn ègé ike àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

1. Rọ omi kí ὁ kún àwọn ike rẹ.

2. Fi ohun èlὸ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sínú ike kọ̀ọ̀kan. Gbọ̀n wọ́n dáradára!

3. Kíni ὁ léfὸὁ? Kíni o rí? Kíni o wà ní àyíká omi?

4. Ya àwὁrán àwọn àbájáde rẹ.

5. Ṣé àpẹrẹ atúnṣé àwọn àbájáde idánwὁ rẹ.

6. Ya àpẹrẹ kan ní abẹ́lẹ̀.

7. Kun àpẹrẹ náà: O ti di Onímọ̀- sáyẹ́ńsì Aǹkárá!