DA OHUN GBOGBO SÍLE KÍ O SÍ YÀWORÁN
Jẹ́ kí a ya àwọn ẹyẹ
Èyí ní díẹ̀ nínú àwọn ẹyẹ tí Afiríka Art.

Ẹyẹ gbígbẹ́ Baga tí a fi igi se láti orílẹ̀ èdè Guinea.

Ilẹ̀kẹ̀ hoopoe láti orílẹ̀ èdè South Afíríkà

Akùkọ Idẹ Benin láti orílẹ̀ èdè Nàijiríà.
Wo àwọn ẹyẹ aláràbarà tí Ilẹ̀ Afiríka wọ̀nyí tí n gbé lόrí tàbí legbẹ́ẹ̀ omi. Gbogbo àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ní o wà nínú ewu nítorí oúnjẹ́ àtí ibùgbé wọ́n wà lábẹ́ ewu opọ̀lopọ̀ ìdọ̀tí.

Ìdì ẹja

Flamingos

Gússì Pygmy Afíríkà
Wo àwọn ẹranko àtí àwọn ẹyẹ ní àyìká rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan ni a ṣe bi όfálì àti bi àpẹrẹ rόbόtό. Bi o bá leè ya àmì rόbόtό kan àtí όfálì kan, o leè ya ẹyẹ! Kíkọ́ ní mimọ̀! Bẹ̀rẹ̀ síi ya àwọn àpẹrẹ ipilẹ ní àkọkọ́.

Bẹ̀rẹ̀ yíyà àwọn iyipo.

Gbìyànjú yíyà àwọn àmì rόbόtό títόbi lόríṣiríṣi àti àwọn ìyípo ὸgidì.

Báyìí, Gbìyànjú pẹ̀lú àwọn àmì όfálì àti ìyípo.

Gbìyànjú yíyà àwọn ìyẹ́ àti àwọn ìyẹ́ ẹyẹ tí o tὸmọ́ra.

Lo àwọn àpẹrẹ tí o rọrùn láti ya àwọn ẹyẹ ní àwọn ipὸ oríṣiríṣi.
Báyìí, o tí di ọ̀gá nínú iṣẹ́ ọnà yìí!



Copyright Polly Alakija