DODDLE ÌṢẸ́JÚ MÁRÙN UN OJOOJÚMO
Àwὁrán ara ẹni

Jẹ́ kí a ya àwὁrán tí ara ẹní. ìwọ yὁὸ nílὸ dígí kan kí o leè rí ààyè wὁ ojú ara rẹ. Bẹ̀rẹ̀ nípa yíyà àwọn àpẹrẹ όfálì.

Ya àpẹrẹ όfálì ńlá kan fún orí rẹ.

Copyright Polly Alakija

Àwọn ojú rẹ wà ní ìdajì ọ̀nà sόkè orí rẹ, àti ìsàlẹ̀ imú rẹ ní agbedeméjì láarín àwọn ojú rẹ àti àgbọ̀n rẹ. Ṣé o ríi? O dára bẹ́ẹ̀! Iṣẹ́ kàn ọ.

Àwọn àwὁrán ara ẹní n sọ fún wa ohun tí o lérὸ nípa ara rẹ.

Copyright Njideka Akunyili

Njideka Akunyili Crosby “Àwọn ohun ìrántí ìgbéyàwὁ”.

Copyright Yinka Quinn

Yinka Quinn “Kὸ sí Ilẹé-ìwé lόnìí”