DODDLE ÌṢẸ́JÚ MARUN UN OJOOJÚMO
Àwọn àgékúrú àpapọ̀ tὁ rẹwà

A ní láti dá fífọ ẹ̀gbin wa sínú àwọn ọ̀nà ojú omi wa dúrὁ. Láìpẹ́ àwọn ike yὁὸ gba gbogbo odὸ àti ὸkun wa wọn yὁὸ sì pọ̀ ju ẹja lọ lẹ́yìn náà kíni a yὁὸ máa jẹ? A n rí àwọn ὸkú ẹyẹ àtí ẹranko pẹ̀lú ìdọ̀tí nínú ikùn wọn. Eja ńlá tὁbi púpọ̀. E jẹ́ kí a fi ojú inú wὁ Báwo ni ìdọ̀tí tí wọ́n n gbé mì yὁὸ se tὁ.

Copyright Polly Alakija
Copyright SCOTTISH MARINE ANIMAL STRANDINGS SCHEME

Ẹja ńlá yìí ní 100kg ike nínú ikùn rẹ̀.

O nílὸ àwọn ojú ìwé mẹ́rin, gbogbo wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kannáà.

Ya ìlà kọjá àarín ewé kọ̀ọ̀kan.

Ṣé àwọn àmì 2 cms àti 4 cms sínú láti ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ìlà àarín yìí.

Ya àwọn ohun mẹ́rin. Àwọn ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlà ìta.

Kíni ό wà nínú àwọn ikùn wọ́n? Awọn ikùn wὁn gbọ́dọ̀ ní ibámu pẹ̀lú àwọn ìlà àarín.

Copyright Polly Alakija

Gé àwọn àwὁrán rẹ lẹ́gbẹ́ẹ̀ ìlà àarín.

Da àwọn ohun tí o sẹ̀dá pọ̀ láti ṣẹ̀dá díẹ̀ nínú àwọn àwὁrán ìgbádùn!