ÈYÍ NI AJÀFITAFITA
Amariyanna Copeny

Copyright LuLu Brezzell

Ọmọ odun mẹ́jọ ni Amariyanna jẹ́ nígbàtí ό bẹ̀rẹ̀ ìpolongo láti dáàbὁ bo omi àwọn ìlú rẹ̀.

IWO NÁÀ GBODO DI AJÀFITAFITA!

Ojúse rẹ nI láti ṣé iyàtọ! Ojúse rẹ ní láti ríi dájú pé àwọn ènìyàn ní agbègbè rẹ kὸ da ìdọ̀tí sínú kanga, odὸ, tàbí kὸto ìdaminù nítorípé wọ́n n bá omi rẹ jẹ́ wọ́n sí n jẹ́ kí o máa ṣàìsàn.

Amariyanna Copeny ni a bi ní ọdún 2007. Ara ìlú Flint ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni. Omi tí o wà ní ìlú tí Amariyanna n gbé kún fún ẹ̀gbin. O kọ̀wé sí Aàrẹ Obama pé kí o ṣàtúnṣé iṣoro náà, Obama sì ṣé e!

Copyright PURPOSE/FOOTAGE FILMS
Copyright Jake May

Wo inú àwὁjiji.

Taani o rí?

Ṣé ìwọ náà leè jẹ́ ajàfitafita?

Kíni o fẹ́ yípadà ní agbègbè rẹ?

Báwo ni ìwọ yὁὸ ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbọ́ tìrẹ? Ṣé ìwọ yὁὸ ṣé àpẹrẹ aṣọ-kékeré, egbà-orí, kọwé sí Aàrẹ? Ìwọ náà leè ṣé bẹ́ẹ̀!

Copyright LuLu Brezzell

GBÁ SÍLE KÍ O SÍ ṢE PDF

Five Cowries
Copyright Polly Alakija

Kíni ìfiráńṣẹ́ rẹ? Jẹ́ kí o rọrùn!