IWO NÁÀ LEÈ ṢEÉ
Apẹja ìdùnnú

Bí o bá jẹ́ apẹja kíni ìwọ yὁὸ fẹ́ láti rí nínú ẹja rẹ? Fojú inú wo bí o se rí lábẹ́ omi. Kíni ìwọ yὁὸ rí? Eja, ike ẹ̀gbin tàbí Mammy Wata? Jẹ́ kí a ṣé àwὁṣe aquarium ohun tí o rὸ pé ὁ wà lábẹ́ omi.

Ìwọ yὁὸ nílὸ:

  • Apọ̀tí páálí àtijọ́
  • Ìwé
  • Ohun àlẹ̀mọ́ra
  • Sísọ́ọ̀sì

A dárà sí àpὁtí yìí nínú pẹ̀lú aṣọ idẹ. O leè kun inú rẹ̀.

1. Ya àwọn àpẹrẹ díẹ̀ nípa ohun tí o rὸ pé o leè rí lábẹ́ omi. Bí o bá lo ohun ìkọ̀wé kékeré tàbí títόbi àwọn àwὁrán rẹ yὁὸ dàbí àmọ́dájú gaan! Lo ìkọ̀wé títόbi fún àwọn ìlànà àkọ́kọ́ kí o lo ìkọ̀wé kékeré fún àwọn àlàyé.

2. Gé àwọn àpẹrẹ rẹ kí o ṣé pááli padà fún àpẹrẹ kọ̀ọ̀kan.

3. Hun “ohun tí o pa” sínú aquarium rẹ.

Copyright Polly Alakija