IWO NÁÀ LEE ṢEÉ
Ẹja tὁ rẹwà

Àwọn ẹja ẹlẹ́wà wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́-ọwọ́ ṣe ní orílẹ̀ èdè Benin Republic. Àwọn ohun élὁ tí a túnlὁ ni wọ́n fi ṣe wọ́n.

Iwọ náà leè ṣeé!

Gbogbo ohun tí o nílὸ ni:

  • Àwọn àpὸ ọlọ́ọ̀rá
  • Apὸ ẹ̀gbin
  • Káàdì ẹ̀gbin
  • Sísọ́ọ̀sì
  • Ohun àlẹ̀mọ́ra

1. Gé àwọn àpὸ ọlọ́ọ̀rá sínú àwọn ìlà kí o dì wọ́n papọ̀ láti ṣe okùn.

2. O nílὸ àwọn ìdínkú kékeré ti ìwé ẹ̀gbin láti ṣe àwọn àpẹrẹ àwọn ẹja rẹ.

3. Se àwọn ègé kékeré ìwé náà sí ìdajì.

4. Ya ìdajì àpẹrẹ ẹja lόrí ègé náà.

5. Bẹ̀rẹ̀ gígé!

6. Ṣé ìtúká ègé náà láti leè ẹja ẹlẹ́wà rẹ!

7. Ṣé àpẹrẹ àtílẹyìn káàdì láti bá ẹja ìwé rẹ mu.

8. Báyìí ṣé àwọn ojú sí ẹja náà!

Copyright Polly Alakija

9. Lẹ ẹja ẹlẹ́wà rẹ pọ̀ mọ́ okùn rẹ.

Báwo ni ẹja rẹ se rẹwà tό?