IWO NÁÀ LEE ṢÉE
Láti ẹ̀gbin sí àwọn Odὸdό ìyàlẹ̀nu
Wo àwọn ὸdὸdό ìyàlẹ̀nu wọ̀nyí tí oníṣẹ́-ọnà ọmọ ilẹ̀ Czechoslovakía, Veronica Richerterová ṣe. Ṣé o rí ohun tí wọ́n fi ṣe àwọn ὸdὸdό náà?



Iwὁ náà leè ṣeé!
Gbogbo ohun tí o nílὸ ni:
Ike omi
Okùn
Sísọ́ọ̀sì
O leè kun àwọn ike náà ṣáájú kí o to bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ríi dájú pé o lo àwọn ọ̀dà olόmi.
Àwọn ìlànà:

1. Gé ìsàlẹ àwọn ike rẹ.

2. Gé àwọn ike náà láti ìsàlẹ̀ sí ὁké láti ṣé àpẹrẹ àwọn irúgbìn ὸdὸdό. O leè ṣe àwọn wọ̀nyí ní gígùn, kúkúrú, tínínrín tàbí títόbi. O leè lọ́ wọn tàbí kí o rọ̀ wọ́n.

3. Hun wọ́n papọ̀ kí o sì so wọ́n kọ́ sόkè. O rọrùn! O leè ṣàfikún àwọn ewé sí okùn náà.


