KÍ LÒ Ń ṢẸLẸ̀ NÍHÌN-ÍN


Copyright Polly Alakija
Awọn ọmọ́dé láti Bádore Model College, Lagos, Nàìjíríà àtí ọkọ̀ ojú-omi wọn “Bellyful”.
Ǹjẹ́ o tí gbọ́ àsà tí wọ́n ńdá “Ìwọ dàbí ohun tí o ńjẹ”? Ohun tí o jẹ tún dá lόrí ohun tí o ńmú. Láti tọ́jú ìlera àtí lágbára o nílὸ láti máa mu ό kéré jù 1.5 lítà omi tí ό mọ́ ní ojúmọ́, àtí pàápàá díẹ̀ síi ní àkόkὸ èèrùn.

Ǹjẹ́ omi rẹ mọ́ nítí gìdí? Èyí ni omi ẹ̀rọ tí a wὁ lábẹ́ máikírόsíkόὁpù.
Níbo ní o tí n gbá omi mímu rẹ? O leè dàbí ẹní pé o mọ́ ṣùgbọ́n àwọn ìdun leè wà nínú omi tí o kὸ leè rí àtí pé tí o bá mu omi náà o le jẹ kí o ṣàìsàn. Ríi dájú pé omi tí o ńmú wà ní sísè fún o kéré jù ìṣẹ́jú kan nítorí èyí yὁὸ pa gbogbo àwọn kὸkὸrὸ inú omi rẹ.

Ṣé omi yìí dàbí aláìléwu? Ṣé o leè jẹ ẹja tí a bá pa nínú omi yìí?
Tí omi rẹ bá ní ìdọ̀tí nípasẹ̀ ẹ̀gbin májèlé, Èyí kὸ leè di mimọ́ nípasẹ̀ sísè nítorí náà o nílὸ láti ṣọ́ra ibití o tí n gba omi rẹ. Tí o bá gba omi láti ibi tí a tí dá ìdọ̀tí sílẹ̀ tàbí níbití àwọn àgbẹ̀ tí n ju àwọn ohun èlὸ apàkόkὸrὸ, o leè ní àwọn kẹ́míkálì nínú, èyí sí leè jẹ kí o ṣàìsàn.

Ṣé o ríi ìdí tí ẹja nlá yìí fi kú?
Bí omi náà bá jẹ́ aláìmọ́ yὁὸ tún jẹ́ kí àwọn ẹja tí n gbé inú omi ṣàìsàn nítorí wọn yὁὸ jẹ ìdọ̀tí. Àwọn ènìyàn n ju ike ẹ̀gbin púpọ̀ sí àwọn oju odὸ wa àtí pé ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sí àsìkὸ tí a wà, àwọn ike ẹ̀gbin tí yὁὸ wà nínú àwọn odὸ wa àtí àwọn okún yὁὸ pọ̀ ju ẹja lọ. Nítorínáà kíni yὁὸ ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwa tí ìdílé wa jẹ́ apẹja?



Ní Nàìjíríà a ní àwọn oríṣi ẹyẹ yọjayọja mẹ́wàá. Àwọn ẹìyẹ́ ẹlẹ́wà wọ̀nyí máa ńmú ẹja, Èyí ní ìdí tí àwọn àgόgό wọn fi gùn bẹ́ẹ̀. Bí omi bá kún fún ike, kíni wọn yὁὸ máa jẹ? Ní gbogbo àgbáyé àwọn ẹranko àtí àwọn ẹyẹ n kú nítorí ikùn wọn kún fún ẹ̀gbin ike. Iṣẹ́̀ rẹ ní àtí gbìyànjú kí o dáàbὁ bo gbogbo wa.






Copyright Polly Alakija