SỌ ÌTÀN RẸ FÚN MI
Șẹ́ẹ po kí o sì túu ká

Pẹ̀lú ẹ̀yìn ìwé rẹ tí o kọjú sí ὸké, se ìsẹ́po láti igun sí igun. Túu lẹ́ẹ̀kansíi.

Ìwọ yὁὸ rí X ńlá kan tí yὁὸ jáde sínú ìwé rẹ.

Sẹ́ igun kọ̀ọ̀kan po títí dé àarín onígun mẹ́rin rẹ.

Onígun mẹ́rin rẹ yὁὸ máa dínkù.

Yi onígun mẹ́rin rẹ padà.

Sẹ́ igun kọọ̀kan pọ̀ sí àarín onígun mẹ́rin rẹ.

Onígun mẹ́rin rẹ yὁὸ túbọ̀ máa kéré síi.

Sẹ́ẹ po kí o sì ṣí onígun mẹ́rin rẹ ní ìdajì àwọn itọsọ̀nà méjèèjì.

Yí onígun mẹ́rin rẹ padà.

Fi ìka rẹ sí ìsàlẹ̀ àwọn ìdérí kí o sì taari àwọn igun ìta sí àarín.

Bí o ṣé le ṣéré:

1. Pẹ̀lú Olùtọ́jú Ìtàn lόrí ìka rẹ, pé ọ̀rẹ́ rẹ kan láti yan àwὁrán kan ní ita tí Olùtọ́jú Ìtàn náà. Ka ọ̀rọ̀ sípéli tí o yàn kí o ṣii, kí o sí tún pa Olùtọ́jú Ìtàn náà dé fún lẹ́tà kọ̀ọ̀kan tí ọ̀rọ̀ náà. Èyí ní ibẹ̀rẹ̀ ìtàn náà.

2. Pé ọ̀rẹ́ rẹ láti yan àwọn nọ́mbá méjì tí wọ́n rí nínú Olùtọ́jú Ìtàn. Ṣàfikún àwọn nọ́mbá méjì papọ̀. Ṣi Olùtọ́jú Ìtàn kí o sì paá dé ní àwọn àkόkὸ yìí. Ìtàn rẹ gbọ́dọ̀ ní nọ́mbá yìí pẹ̀lú.

3. Ọ̀rẹ́ rẹ gbọ́dọ̀ yan nọ́mbá mìíràn.

4. Ṣí ààyé ìdérí Olùtọ́jú Ìtàn lábẹ́ nọ́mbá yìí kí o sí wo irú àwὁrán tí ὁ wà níbẹ̀. Àwọn àwὁrán tí o bá rí níbẹ̀ ní yὁὸ ṣé ìparí ìtàn náà.

GBA DUN!

Ṣe igbasilẹ ati Ṣe!

Five Cowries
Copyright Polly Alakija

O le tẹjade ati ṣe igbasilẹ olutọju itan rẹ nibi, tabi o le ṣe apẹrẹ tirẹ!