GBA AWỌN KIKUN JADE
Íhó-ọṣẹ Àti Kòkòrò
Fún ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún ni àwọn ènìyàn ti ń ya àwòrán ọwọ́. Nínú àwọn ihò-ilẹ̀ ní jákèjádò ayé, a óò rí àwọn àwòrán ọwọ́ àdáyébá.

A sì tún ń gbádùn láti máa ya ọwọ́ ní ọjọ́ òní !


Copyright Polly Alakija
Kó ọ̀dà jáde! Jẹ́ kí a kun àwòrán tí yóò rán wa létí láti fọ ọwọ́ wa pẹ̀lú ọṣẹ púpọ̀ kí ó lè ṣe ìdènà kòkòrò nì.
O ó nílò:
1. Ọ̀dà olómi mẹ́ta tí aró wọn yàtọ̀ síra wọn.
2.Ìwé pélébé kan.
3.Gègé ìkọ̀wé àti búrọ̀ṣì
