ÌWỌ NÁÀ LÈ ṢE É
Íhó-ọṣẹ !

Rántí láti fọ ọwọ rẹ pẹ̀lú ọṣẹ púpọ̀ nígbà gbogbo.
Jẹ́ kí a gbẹ́ ère El Anatsui tí ó ṣe ìrántí íhó-ọṣẹ púpọ̀fún wa. O ó nílò :
Ìgò omi oníke, ègé aṣọ kéékèèké, sítáàsì, àlùjámọ́ pẹ̀lú okùn tẹ́ẹ́rẹ́tàbí ọsán.
Ìtósónà :
1. Gé ike omi sí ìrísí òrùka.

2. Gé aṣọ kéékèèké bíi ojú ọwọ́ kan/sẹ̀ntímítà méjì.
3.Rẹ àwọn ègé aṣọ náà sínú sítáàsì kí o sì wé wọn mọ́ àwọn ìrísí òrùka tí ike omi tí o gé.


Copyright Polly Alakija
4. Ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ ti ìrísí òrùka ti ike omi, kí o sì so wọ́n papọ̀ pẹ̀lú okùn tẹ́ẹ́rẹ́


Àwọn oníṣẹ́ ọnà mìíràn gba ìmísí láti ọwọ El Anatsui.