ÌWỌ NÁÀ LÈ ṢE É
Iṣẹ́ Àlẹ̀mọ́

Àwọn àrà àti ìgbékalẹ̀tí ó wà lára àdìrẹ Ẹlékọ máa ń sọ ìtàn.

Adire Eleko : Ibadan, Nigeria

Oríṣiríṣi aṣọ aláró jẹ́ ohun tí a mọ̀ mọ́ìpínlẹ̀ Kano àti Ọ̀yọ́. Ara igi aró tí ń hù ni àwọn ìpínlẹ̀ kan ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ati máa ń rí aró.

Copyright https://collection.maas.museum/

Ìṣẹ́-ọnà olóòwú láti ìpínlẹ̀ Kano ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

A ó fi iṣẹ́ àlẹ̀mọ́ sọ ìtàn nípa lílo àwọn èròjà tí a lè rí ní àyíká wa. 

O ó nílò:

1. Aṣọ bíi àbọ̀-ọ̀pá tí ó dọ́gba.  

2. Okùn, okùn tẹ́́rẹ́tàbí ọṣán, ilẹ̀kẹ̀, bọ́tìnì, àti àwọn ègé aṣọ kéékèèké.

3. Abẹ́rẹ́ àti òwú.

Copyright Polly Alakija

Ìtọ́sọ́nà 

1. Ní àkọ́kọ́, ya àgbékalẹ̀ rẹ sínú ìwé.

3. Ṣe àgbékalẹ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ègé aṣọ.

5. Tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlúmọ̀ rẹ bá ṣe ìgbékalẹ̀ onígun mẹ́rin tiwọn, ẹ lè pawọ́n pọ̀láti sọ ìgbékalẹ̀ yín di ńlá.

2. Gé aṣọ bíi àbọ̀ -ọ̀pá onígun mẹ́rin. 

4. !Bẹ̀rẹ̀ síní ran-an. Fi bọ́tìnì pẹ̀lú ilẹ̀kẹ̀tàbí ohunkóhun tí ó rí sí-i !

Copyright Polly Alakija

Copyright Bamigbade Gafar Babatunde

” It’s In Your Hands ” by Sarah , Ogun State, 2020