PADE ONISE
El Anatsui

EL Anatsui jẹ́ agbẹ́gilére ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana. 

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wà ní ilé-ọnà ati àwọn ibi  ìṣàfihàn àwòrán káàkiri àgbáyé.

Copyright El Anatsui

Yíò sì máa gbẹ́ ère pẹ̀lú àwọn ohun tí o wà ní àyíká rẹ̀. El Anatsui kò gbàgbọ́ nínú fifi owó iyebíye ra ohun èlò fún iṣẹ́-ọ̀nà aláràmbarà. 

Copyright El Anatsui

Yíò sì máa fi ìdérí ọtí, agolo àti àwọn aṣọ tó ti gbó ṣe iṣẹ́-ọnà. Yíò di àwọn ohun èlò tí ó bá rí pọ̀ kí wọ́n lè dàbí aṣọ.

Copyright El Anatsui

 Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn ní ìrísí wúrà, bẹ́̀ ohun tí ó fi ṣe wọ́n  kò kọjá agolo àti ìdérí ọtí.