KÍ LÒ Ń ṢẸLẸ̀ NÍHÌN-ÍN
Kí ni à ń fi ọwọ́ wa ṣe?


A máa ń fi ya ǹkan, kọ̀wé àti dáná. A máa ń fi gbé ǹkan sókè-sódò. A máa ń fi ọwọ́ wa gbé ọmọ, a sì tún máa ń fi di irun.
A máa ń gbọwọ́láti kíni kú àbọ̀, a sì máa ń juwọ́láti sọ pé ódàbọ̀.

Nelson Mandela meets the United Nations Secretary General in Portugal in 1993.
Yẹ ọwọ́ rẹ wò fínnífínní. Ṣé wọ́n mọ́ dáadáa? Kí ni o gbé dání? Ṣé o lè ya àwòrán ohun tí o lè rí àti àwọn èyí tí o kò lè rí?

Àwọn kòkòrò àìsàn kéré gidi gan. O kò lè rí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n wà níbẹ̀. Àwọn kòkòrò àìsàn yìí wà ní ọwọ́ilẹ̀kùn, tábìlì, ìjókòó ọkọ̀ àti nínú àpò alágbèéká, tí wọ́n dúró kí o lè kó wọn!

Ní gbogbo ìgbà tí o bá sín tàbí wúkọ́, o lè ṣe àtàkáa kòkòrò náà tí o bá ni-i. O lè tàn ká ní kíákíá kódà dé ibùsọ̀ méje.
