NỌ̀Ọ̀TI ÀTI BόὸTU
Kíni ìdí?

Kiní ìdí ti ọṣẹ fi n pa àwọn kὸkὸrὸ àrùn?

Ìwọ yόὸ nílὸ :

Omi,

Ata gbigbẹ

Ọṣẹ ìfọ àwo

Ikọ̀wé àti ìwé

1. Fi omi kékeré sínύ àwo rẹ.

2. Wọ́n ata sínύ omi rẹ. Ṣé o ríi bí ό ṣe nfὸ lόjύ omi? Èyi wáyé nítorí pé ẹ̀dọ̀fù tό wà lόrí omi jẹ́ ki ό léèfόfό.

3. Ti ìka rẹ̀ bọ ínύ àwo omi àti ata. Njẹ́ ohunkόhun ṣẹlẹ̀? Fojú inú wo àwọn ọmọ ata gẹ́gẹ́ bi kὸkὸrὸ. Njẹ́ diẹ̀ nínú àwọn ọmọ ata náà lẹ̀ mọ́ ìka rẹ?

4. Báyìí, fi ìka rẹ bọ ínύ omi ọṣẹ àti lẹ́yin náà fi ìka rẹ padà sínύ omi.

5. Kiní o ṣẹlẹ̀ ní àkόkὸ yìí nígbàti o fi ìka ọṣẹ rẹ sínύ omi? ! Ọṣẹ náà leè pa àwọn kὸkὸrὸ àrùn inú ata! .Ọṣẹ máa nfὸpin si àifọ̀kànbalẹ̀ ti omi èyí ní ìdí tí o fi leè pa àwọn Kὸkὸrὸ àrùn. Èyi ní ìdí ti o fi gbọdọ̀ máa wẹ ọwọ́ rẹ nígbà gbogbo pẹ̀lú ọṣẹ!

Gbogbo àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tό dára àti àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ ni wọn nṣe àkiyèsi ti àwọn ìwádìí wọn.  o leè ya àwὸrán iṣẹ́ ìwádìí ọṣẹ rẹ?

Copyright Tolu Ami-Williams and Sifon Ediomoo-Abasi

Èyi ní àwὸrán nlá ti ọṣẹ ìfọwọ́ àti àwọn kὸkὸrὸ àrùn, báwo ni àwὸrán rẹ yόὸ ṣe rí?