KINI ό N ṢẸLẸ̀ NÍBI?
Àwọn irinṣẹ wo ní ìwọ yόὸ nílὸ?
Gba àwọn ohun ti àwọn ọmọ rẹ leè lὸ láti ṣe àwọn nǹkan pẹ̀lú. Àwọn ike omi, asọ ègé, àwọn ìdéri ike omi, okùn, àwọn bọtiní, ìwé àtijọ́ àti àwọn ìwé ìrὸhin.

Jẹ́ ki àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni ìpamọ dáradára lọ́nà tí o mọ́. Lo àpόti ti ό yàtọ̀ fún ohun kọ̀ọ̀kan ti o ń gbà.

Fún àwọn ọmọ rẹ ní ẹní kan, ki o ṣe èyí ní “ẹní ẹ̀kọ́”.

Àwọn ọmọde wọ̀nyí nlo ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ bi ẹní ẹ̀kọ́ wọn.
Fún àwọn ọmọ rẹ ní àkόkὸ pàtό ti a ṣètὸ ní gbogbo ọjọ́ nígbàti wọ́n leè ṣe àwọn iṣẹ́ lόrí “ẹní ẹ̀kọ́”.
Àwọn ọmọdé gbọdọ̀ jόkὸό nígbà gbogbo nígbàti wọ́n bá ǹ gé nǹkan. Máṣe lo ohun ègé láti tọ́ka sí ẹníkan tàbi nǹkankan. Nígbàti o bá gbá ohun ègé mú, “ẹnu” rẹ̀ gbọdọ̀ wà ní ọwọ́ rẹ.

O jẹ́ ohun ńlá ti àwọn ọmọ rẹ bá ńṣe irànlọ́wọ́ ní ilé, ní oko tàbi ní ọjà. .Jẹ́ ki àwọn ọmọ rẹ máa ṣe ìgbàsílẹ̀ gbogbo àwọn iṣẹ́ ti wọn ńṣe ní ilé ki o si máa ṣe àpọ́nlé wọn nígbàti iṣẹ́ ọwọ́ wọn bá kún.
Máa rán àwọn ọmọ rẹ léti láti máa wẹ ọwọ́ wọn ṣáájú àti lẹ́yìn èyikéèyi iṣẹ́ ti wọ́n bá ṣe.
Ti o bá ní ìwé akọsílẹ̀ kan ṣe ìwé iránti ìdílé . Lὁjoojύmọ́ pe àwọn ọmọ ẹbí láti kọ tàbi ya àwὸrán nípa nǹkan tàbi ohun ti o ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà.. Gbogbo ẹbí leè ṣe èyi!
Ṣe ayẹyẹ ìdílé rẹ nípa yiya igi ìdílé papọ̀.

Copyright Polly Alakija
Ṣe ìgbàsílẹ̀ ki ό si pe ọmọ ìdílé kọ̀ọ̀kan láti ya àwὸrán ara wọn sínú igi ẹbí yìí.