Ọ̀RỌ̀ SISỌ COTONOU

 Káàbọ̀ Stéphane! Bonjour Stéphane!

Stéphane wa láti Cotonou. Stéphane n sọ Faransé.

Copyright Poly Alakija

O fẹ́rẹ́ to àwọn ènìyàn miliọ̀nù ὸjiléniọgọ́ọ̀rún ni Afirìka ti o n sọ Faransé ní àwọn orilẹ̀-èdè mẹ́tàlélọọ́gbọ̀n .A mú èdè Faransé wa sí Afirikà nípasẹ̀ ijọba amúnísín. Cotonou jẹ ilú ti o tobi jùlọ ní Orilẹ̀-Edè Benin. .O wa láarin Okun Atlantiki àti Adágun Nọkọ̀ué.

Copyright Gille C Photography

Ẹja jẹ́ oúnjẹ́ pàtàki ti àwọn ènìyàn Orilẹ̀-Edè yii máa njẹ. Oúnjẹ́ ní Ilẹ̀ Benín jẹ́ àdàpọ̀ ti àwọn adùn Afirìka, Brazil àti Yúrόὸpù. .A leè jẹ́ ẹja yiyan pẹ̀lú obẹ̀ Mὸyόὸ èyi ti a ṣè pẹ̀lú tomáàti àti ata tàbi o le jẹ́ Ago Glain, ipẹ̀tẹ̀ ti a ṣe pẹ̀lú ẹja-igi àti pẹ̀lú fùfú.

Copyright IRD/C. Lévêque

Olú ilú orilẹ̀-èdè Benín ni Porto Novo.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé àṣà ilú Brazíl àtijọ́ lό wà ní Porto Novo, Awọn ọmọ Afirìkà ti o padà dé lati ilú Brazíl lό kọ́ ilé wọ̀nyi.

Copyright Musa Jibril

Ilú yii bẹ̀rẹ̀ bi agbègbè ipẹja ṣùgbọ́n ό di àarin pàtàki fún isὸwὸ. Àwọn ὸwὸ miiràn agbègbè náà ni ẹrú, epo ọ̀pẹ̀ àti ὸwú.

Copyright Happy Days Travel Blog