Ọ̀RỌ̀ SISỌ LAGOS
Ọ̀RỌ̀ SISỌ : ÈKÓ
Káàbọ̀ Timilayo! Ekaro Timilayo!
Timilàyo n ṣiṣẹ́ ní Alliance Française Lagos.

Timilàyo gbọ́ YORÙBÁ. Enìyàn miliọ̀nù márùn ύn dinlàáádọ̀ta ni wọn n sọ Yorùbá ní orilẹ̀èdè Naijiria àti káàkiri àgbáyé . Ekὸ wà nítosí equator nítorí náà o gboná ní gbogbo ọdún!. Ilú Ekὸ ní ọ̀kan nínú àwọn ibùdό ọkọ̀ ojύ omi ti o sisẹ́ jùlọ ni Afirìka . Àwọn ọmọ Yorùbá ti n gbé níhin láti ọ̀rúdún kárùn ύn dinlόgύn, O ti di ilé fún àwọn ènìyàn ti ẹ̀yà oríṣiriṣi láti gbogbo orilẹ̀-èdè Naijiria, Láti Ìwọ̀-oὸrùn Afirìka àti fún àwọn ẹrú àtijọ́ ti ό padà dé láti Ilú Brazil àti West Indies.
Àwọn ènìyàn ti n gbé ní EKὸ je miliọ̀nù mọ́kànlélόgún.Orúkọ náà “Lago” túmọ̀ sí “adágún” ní èdè Pọtogi. Ọdún 1470 ni àwọn onísὸwὸ ilú Pọtogi kọ́kọ́ dé sí Ekὸ..Ekὸ di ibùdό ọkọ̀ pàtàki fún ὸwὸ ẹrú . Ilú Ekὸ di agbègbè Ijọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí ní ọdún 1862. O di olú-ilú Naijiria o sí wà bẹ́ẹ̀ lẹ̀yin ὸminíra ní ọdún 1960.. .Ní ọdún 1991 ijόὸkό ijọba lọ sí Abuja ṣùgbọ́n Ekὸ dúrό bi olú-ilú ὸwὸ Naijiria.

Àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé máa n jo sí orín afrobeat ti Fela Aníkulapo Kuti n kọ nínú “The Shrine” ní ilú Ekὸ

Èyi ní Aso Eka ti Ipinlẹ̀ Ekὸ.

Aso Eka leè sọ itàn.
Filà funfun “Kerẹrmesí” dúrό fún Àwọn Olόyè Ibilẹ̀ ti Ipinlẹ̀ Ekὸ.

Ní igbà kan Ilú Ekὸ jẹ́ ilé fún àwọn apeja, oko ata àti oko àgbọn..Pẹ̀lú omi àti àwọn eti ὸkun ti ό yi Ekὸ ká, àwọn ìka rahun àti owό ẹyọ ní a n lo láti sanwό ọjà àti kátàkárà.