Ọ̀RỌ̀ SISỌ KANO

 Káàbọ̀ Fatima!  Sannu Fatima! 

Fatima n ṣiṣẹ́ ní Alliance Française ti Kano.

Copyright Polly Alakija

Fatima ń sọ Hausa. Hausa ní èdè abiníbi ti a n sọ jùlọ ninu àwon èdè abiníbi Afirikà. O fẹ́rẹ̀ to ènìyàn miliọ̀nù ọgọ́ọ̀rúnléláàádọta ti ń sọ Hausa.Àwọn èdè oríṣiriṣi àdúgbὸ wà ní àwọn agbègbè púpọ̀ bi Ghana, Chad àti Cameroon.

Kano ní ilú ẹlẹẹkeji tí o tobi jù ni Naijiria.  jẹ́ ilú àtijọ́ ti o jẹ́ pàtàki fún isὸwὸ ni agbègbè asalẹ̀ ti sahara fún àimọye ọ̀rúdún.Ní ọ̀rúdún kejilà, ilú Kano di ilú to ni ààfin.Ní ọ̀rúdún kọkàndinlόgún ilú Kano di Emirate ti Caliphate Sόkόtό.Awon odi to lágábara to fi igbà kan yi ilu náà ká. Diẹ̀ nínú àwọn apákan ti àwọn ogiri náà wà ni a tún leè rii.

Copyright Creative Common

Ní ilú àtijọ́ yìí a tún leè ri àwọn kὸtὸ arό àṣà ibilẹ̀.

Copyright Creative Common

.Ní ọdọọún ni Emir ti Kano nṣe àpéjọ Durbar láti ṣe ayẹyẹ Eid al-Fitr àti Eid al-Adha.

Copyright Don Camillo